Ọwọ tẹ ayederu alaga ẹgbẹ oṣelu Action Alliance l'Ebonyi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 19, 2021

Ọwọ tẹ ayederu alaga ẹgbẹ oṣelu Action Alliance l'Ebonyi


Ileeṣẹ awọn ọlọpaa ni Ebonyi, ti mu ọkunrin afurasi kan, Godwin Ukwu,lori ẹsun pe o pe ara ẹ ni alaga fẹgbẹ oṣelu Action of Alliance, A A nipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ṣe ni ọkunrin ayederu alaga ọhun ṣi ọfiisi kan lorukọ ẹgbẹ naa ni Abakaliki, to si tun dari awọn igun kan ninu ẹgbẹ yii.

Iwadii fi ye wa pe wọn mu ọkunrin lẹyin to ti kọkọ sa lọ ṣugbọn ti ọwọ tẹ ẹ, ti si ti wa ni agodo awọn ọlọpaa ni Abakaliki, nibi ti kọ awọn nnkan to mọ nipa ẹsun ayederu alaga ti wọn fi kan an.

Ninu atẹjade ti Ọnarebu Adekunle Rufai Ọmọaje,alaga lapapọ ẹgbẹ oṣelu AA lorileede yii fi sita lo ti fidi iṣẹlẹ ọhun han, o tan imọlẹ si i pe wọn ti mu Ukwu, o si ti fẹnu fẹ abẹbẹ nibi ti wọn fi pamọ si.

Lọsẹ to kọja yii ni Ọmọaje ṣaaju awọn oloye ẹgbẹ lapapọ lọ si Abakaliki, nibi ti wọn ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣeli AA. Bẹẹ la tun gbọ pe titi di akoko yii, wọn ko ti rẹni gba beeli afurasi ayederu alaga ọhun.

Iroyin to tuntẹ wa lọwọ fi ye wa pe gbogbo ọna lawọọ oloye ẹgbẹ oṣelu yii gba lati ri pe wọn mu Ukwu, to si n ṣe faaji lọwọ ni teṣan awọn ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI