Lásìkò ta a pari iroyin yii, jinnijinni nla lo ti ba t'ọmọde t'agba ipinlẹ Kwara lori bi wọn ṣe n da idọti s'awọn opopona kaakiri ipinlẹ naa.
Ana ti i ṣe Tuisdee ni ijọba ipinlẹ naa labẹ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq bẹrẹ gbigbe awọn apoti ikolẹsi s'awọn opopona kaakiri f'awọn eeyan lati maa da idọti wọn sí.
A gbọ pe lojuna lati dẹkun omiyale, agbara-ya-ṣọọbu nijọba ṣe bẹrẹ eto yii i pẹrẹu, ati lati dena ajakalẹ arun.
Nigba to n gba ẹnu Gómìnà AbdulRazaq soro, Banigbe Rẹmilẹkun Oluwatobi to jẹ kọmiṣanna fun ọrọ eto ayika ati agbegbe sọ pe awọn ti bẹrẹ si i gbe ile idalẹnu alagbeeka s'awọn opopona kaakiri fun anfaani araalu lati maa da ilẹ ati idọti sibẹ, pẹlu erongba lati fọ ipinlẹ Kwara mọ.
Ile idalẹnu alagbeeka naa to pe ni RoRo la gbọ pe wọn ti gbe s'awọn agbegbe bi i Maraba, Post Office, Gada/Taiwo Isale ati Challenge lanaa, eyi to ku ni wọn fẹẹ tẹsiwaju lonii.
Gbogbo àwọn tí wọn ko bá ṣe àmúlò àwọn ile idalẹnu alagbeeka yii, to jẹ pé wọn ṣi n sọ idọti kaakiri popona ni wọn ló ṣeé ṣe ki wọn foju winna ofin ijọba.
No comments:
Post a Comment