Nitori Idanwo Wọn: Awọn akẹkọọ gbe oṣuba kare fun Gomina Abdulrazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 26, 2021

Nitori Idanwo Wọn: Awọn akẹkọọ gbe oṣuba kare fun Gomina Abdulrazaq


Gbogbo awọn akẹkọọ patapata kaakiri ipinlẹ Kwara, paapaa awọn ti ile ẹkọ poli ni wọn ti n gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun bo ṣe tete da si ọrọ wọn l'ori idanwo to n lọ l'ọwọ.
 
L'aipẹ yii l'awọn alakoso ile ẹkọ gbogboniṣe t'ipinlẹ Kwara to wa n'ilu Ilọrin sọ pe gbogbo awọn akẹkọọ ti ko ba ti san owo ileewe wọn ko ni l'anfaani lati kopa ninu idanwo ti wọn fẹẹ bẹrẹ.

Ọrọ naa da oriṣiriṣi awuyewuye s'ilẹ kaakiri ipinlẹ naa, eyi ti wọn lo o mu k'awọn akẹkọọ kan kọ iwe ẹsun ranṣẹ si gomina AbdulRazaq, ti wọn si n bẹ ẹ lati ba wọn da si ọrọ naa.

Bi ọrọ yii ṣe tẹ gomina AbdulRazaq l'ọwọ lo ti paṣẹ f'awọn alakoso ile ẹkọ gbogboniṣe naa wi pe ki wọn gba gbogbo awọn akẹkọọ naa, iyẹn awọn ti ko ti i ri owo san lati kopa ninu idanwo.
 
Gomina AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ sọ pe "Mo ti ṣe agbeyẹwo nnkan to n lọ naa, mo si ti yẹ iwe ẹbẹ t'awọn akẹkọọ fi ranṣẹ si mi wo daadaa. Mo bu ọwọ lu iwe ẹbẹ naa wi pe ki gbogbo awọn akẹkọọ ti ko ba ti i san owo ileewe wọn lọ kopa ninu idanwo to fẹẹ bẹrẹ naa.
 
N'igba t'awọn naa n fi ẹmi imoore wọn han, ẹgbẹ awọn akẹkọọ n'ipinlẹ Kwara ti wọn pe ni National Association of Kwara State Students (NAKSS) ti Kọmureedi Adekunle Raphael Popoọla jẹ Aarẹ wọn sọ pe awọn ko le ṣai ma dupẹ lọwọ gomina ẹlẹyinju aanu mẹkunnu l'ori igbeṣẹ yii, to si ni titi aye l'awọn yoo maa ranti ipa rere to n ko kaakiri ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI