Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pé igi diẹ lo ku lati mu ai sí ètò ààbò tó péye lọ s'opin igbagbe lorilẹ ede Naijiria, to sì ni gbogbo eto lo ti fẹẹ pari.
Ana ti í ṣe Tusidee ni Gomina AbdulRazaq sọrọ yii nilu Ìlọrin nibi ayẹyẹ igbaniwọle àwọn èèyàn tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gba s'ẹnu iṣẹ ọlọpaa, ìyẹn àwọn ọlọpaa agbegbe n'ipinlẹ náà.
Gomina AbdulRazaq sọ pé k'awọn araalu gbaruku ti Ààrẹ Muhammadu Buhari ati awọn Ileeṣẹ eleto aabo káàkiri orílẹ̀-èdè yii lati kẹsẹjare.
"Àní láti máa f'ọwọsowọpọ pẹlu awọn eleto aabo. Ko si àríyànjiyàn níbẹ pe ipinlẹ Kwara nikan ni ipinlẹ to ní eto ààbò julọ l'orilẹ-ede Nàìjíríà lonii nitori iṣẹ ti wọn n ṣe ni. Bi a ṣe fẹ kó máa rí nìyẹn. Fún ìdí èyí, a ni láti máa f'ọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro. Àsìkò ipenija la n la kọja lásìkò yii, ṣugbọn gbogbo rẹ yóò d'ohun igbagbe laipẹ."
No comments:
Post a Comment