Wẹrẹ bayii ni aṣiri naa tu s'ijọba ipinlẹ Kwara l'ọwọ wi pe awọn oṣiṣẹ ti wọn da duro l'ọdun to kọja, iyẹn awọn olukọ ti wọn pe ni Sunset Teachers labẹ ileeṣẹ SUBEB to n ṣakoso ọrọ eto ẹkọ n'ipinlẹ naa ṣi gba owo oṣu.
A gbọ pe awọn oṣiṣẹ naa ti wọn ko din ni mejidinlaadọta ni wọn gba owo oṣu fun oṣu kẹta ọdun yii, eyi to jẹ iyalẹnu fun ijọba ipinlẹ naa labẹ iṣakoso AbdulRahman AbdulRazaq, to si pinnu lati gbe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹta kan kalẹ lati tọpinpin awọn to wa nidi bi wọn ṣe san owo oṣu naa.
Amofin Saka Razaq ni alaga igbimọ naa, nigba t'awọn bi i Amofin Murtala Sambo ati Arabinrin Adenikẹ Ojo jẹ ọmọ igbimọ.
N'igba ti wọn n jabọ iwadii wọn fun Gomina laipẹ yii, wọn ni gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati f'ọrọ wa lẹnu wo, tonikaluku si sọ nkan ti wọn mọ nipa bi owo oṣu naa ṣe jẹ sisan.
Wọn ni ninu ọrọ t'onikaluku wọn sọ l'awọn ti mọ ibi ti ọrọ naa ti wọ wa, ti wọn si lo o ku s'ijọba lọwọ lati gbe igbesẹ to ku.
Gomina AbdulRazaq n'igba toun naa n sọrọ sọ pe ẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, tori pe awọn yoo gba gbogbo owo naa l'ọwọ ẹ ko to di pe awọn tun mọ igbesẹ to kan lati ṣe.
No comments:
Post a Comment