Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko sí oṣiṣẹ ipinlẹ naa to gba owó oṣù to kere sí ẹgbẹrun lọnà ọgbọn naira, to si l'awọn to n gbe ayederu iroyin kaakiri ko mọ nnkan ti wọn n sọ.
Laipẹ yii ni agba akọroyin kan, Bayọ Ọnanuga gbe apilẹkọ kan jade nipa iṣakoso Gomina Nasir El-Rufai, paapaa lori ọrọ owo oṣù awọn oṣiṣẹ. Níbẹ lo si ti mẹnuba awọn ipinlẹ to sọ pe wọn ko ti maa san ẹgbẹrun lọnà ọgbọn to jẹ owo oṣù tó kere julo, eyi ti Kwara wa lara wọn.
Bi apilẹkọ naa ṣe tẹ ijọba Kwara lọwọ ni wọn ti sọ pe Kwara ọrọ naa ko ri bẹẹ rara, ati pe lati gbogbo oṣiṣẹ Kwara patapata ni wọn n gba ẹtọ wọn lasiko to yẹ
No comments:
Post a Comment