Kwara: Ẹgbẹ oṣelu APC l'awọn ṣetan lati gba ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 8, 2021

Kwara: Ẹgbẹ oṣelu APC l'awọn ṣetan lati gba ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress n'ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọ ṣetan lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun s'inu ẹgbẹ naa, tori pe alaafia ti pada sinu ẹgbẹ wọn, wọn si ti wa n'iṣọkan.
 
Ana ti i ṣe Ọjọbọ-Tọsidee ni alaga fidihẹ ẹgbẹ naa, Abdullahi Samari sọ eyi di mimọ l'ẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu igbimọ kọtẹmilọrun ti wọn gbe kalẹ lati ri si eto iforukọsilẹ ti wọn ṣe kọja.
 
O l'awọn ti ṣetan lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle kaakiri gbogbo wọọdu idibo to wa l'awọn ijọba mẹrindinlogun n'ipinlẹ naa. Bẹẹ lo sọ pe eto iforukọsilẹ naa ṣi n lọ l'ọwọ, ati pe yoo ṣi maa lọ titi d'asiko ti eto idibo ba wọle de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI