Gomina ana nipinlẹ Kwara, Ahmed Abdulfatah la gbọ pe o ti foju ba Ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu l'orilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
Ana ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe Abdulfatah Ahmed lọ jẹ ipe awọn EFCC ni olu ileeṣẹ wọn to wa nilu Abuja.
Nnkan bi aago mẹwàá aarọ la gbọ pe Abdulfatah debẹ, to si lo ọpọlọpọ wakati níbẹ lati rojọ.
Owo kan ti wọn sọ pe ko din ni biliọnu mẹsan naira ni wọn sọ pe Abdulfatah gbe kuro ninu apo ijọba Kwara lasiko to wa ni gomina, eyi si la gbọ pe o fa a ti àjọ EFCC fi ranṣẹ pe e lati wa a sọ t'ẹnu ẹ.
Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ EFCC lo fidi rẹ múlẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sọ idi pataki nnkan tàwọn pe Abdulfatah fun.
No comments:
Post a Comment