Alaga apapọ f'ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Uche Secondus ti pariwo sita pe inu wahala ati idaamu nla ni orile-ede Naijiria wa, to si ni k'awọn ọmọ orilẹ-ede yii maa kiyesara pupọ ninu ohunkohun ti wọn ba n ṣe.
Secondus lo s'ọrọ yii ninu ọrọ rẹ fun ọdun Itunu Aawẹ ti yoo pari l'onii, to si ni aisi eto aabo l'orilẹ-ede yii n kan gbogbo agbaye lominu pupọ.
Ninu ọrọ rẹ naa lo ti gb'awọn eeyan lamọran pe ki wọn tubọ maa gb'adura fun alaafia aabo to peye l'orilẹ-ede yii.
O ni l'atigba ti Naijiria ti bẹrẹ ijọba alagbada l'ọdun, iru awọn nnkan to n ṣẹlẹ l'asiko yii ko waye ri, to si lo o gb'adura pupọ f'awọn adari wa toootọ.
Bakan naa lo ni l'atigba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti gba ijọba l'ọdun mẹfa s'ẹyin, wahala naa ti pọ kọja sisọ, to si nilo adura lati jẹ ki Naijiria yege.
O wa a sọ pe Aawọ ọgbọ ọjọ t'awọn ẹlẹsin musulumi naa gba ko gbọdọ lọ l'asan lai gb'adura fun Naijiria at'awọn adari rẹ ti wọn jẹ olotitọ.
No comments:
Post a Comment