Owo ti ko din ni aadọta miliọnu naira l'awọn ajinigbe ti wọn ji akẹkọọ yunifasiti ọgbin to wa l'Abẹokuta, iyẹn FUNAAB ne beere l'ọwọ awọn eeyan ẹ ki wọn to le fi silẹ.
Ki i ṣe akẹkọ FUNAAB naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Toyinbo Ọlayinka nikan l'awọn ajinigbe yii jigbe l'opin ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ Satide. Wọn tun ji awọn meji mi in naa gbe.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Ọlayinka lọ ọ ṣiṣẹ ninu oko to ti n ṣiṣẹ labule Itoko to wa n'ijọba ibilẹ Ọdeda l'ọjọ naa ni ko to di pe awọn ajinigbe naa yawọ inu oko yii.
Bi wọn ṣe yawọ inu oko naa ni wọn ti yọ ibọn si Ọlayinka ati ẹni to ni oko naa ti wọn pe ni Dominic pelu ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn l'ọmọ orilẹ-ede Togo ni, ti wọn si ji wọn gbe salọ.
Owo ti ko din ni aadọta miliọnu naira la gbọ pe wọn n beere lọwọ akọwe inu oko naa lati fi gba ẹnikọọkan wọn silẹ, tabi ki wọn pa wọn danu lai jẹ pe wọn ko owo naa sile f'awọn.
Bẹ o ba gbagbe, l'Ọjọbọ-Tọside to kọja yii kan naa ni wọn ji oṣiṣẹ fasiti Tai Ṣolarin, Arabinrin Lateefat Abimbọla gbe, ti wọn si l'awọn to ji i gbe ko ti i pe lati beere owo titi ta a fi pari iroyin yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lati gba awọn eeyan naa silẹ laipẹ.
No comments:
Post a Comment