Gomina Abiọdun fẹẹ b'awọn Musulumi ṣinu aawẹ l'Abẹokuta lonii Satide - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 8, 2021

Gomina Abiọdun fẹẹ b'awọn Musulumi ṣinu aawẹ l'Abẹokuta lonii Satide


Gbogbo eto lo ti pari patapata fun gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun lati ba gbogbo awọn Musulumi jakejado ipinlẹ Ogun ṣinu aawẹ Ramadaani t'onii.
 
Gbagede Arcade to wa ni Oke-Mọsan n'ilu Abẹokuta la gbọ pe eto naa ti fẹẹ waye, bẹrẹ lati aago mẹrin irọlẹ onii Satide-Abamẹta.
 
Eto naa ti wọn pe akori rẹ ni 'Idunkoko mọ Eto Aabo Orilẹ-ede ati Iṣọkan: Ẹsin gẹgẹ bi ọna abyọ tabi iṣoro', "Threat to National security and unity: religion as a panacea or problem" la gbọ pe gbajumọ amofin lati ipinlẹ Kwara ni yoo ṣe idanilẹkọọ f'awọn eeyan.
 
Adajọ agba to jẹ Kadi t'ile ẹjọ Sharee'ar n'ipinlẹ Kwara, Abdul Raheem Ahmad Sayi ni oludanilẹkọọ. 
 
Irọrun la gbọ pe jijẹ ati mimnu ba de l'ẹyin ti eto naa bari, ta a si gbọ pe ni ibamu pẹlu alakalẹ lati dena ajakalẹ arun korona ni wọn yoo fi gba awọn l'alejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI