Ọkan lara awọn gbajugbaja oṣere tiata Yoruba nni, Olumide Ọlajide l'ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ bayii l'ori ẹsun jibiti. Wọn ni ayederu owo ni Ọlajide fi n lu awọn eeyan ni jibiti.
Ana ti i ṣe ọjọ Aje-Mọnde n'ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ to wa l'agbegbe Akinyẹle n'ilu Ibadan f'oju Ọlajide pẹlu awọn ọdaran kan han f'awọn akọroyin ipinlẹ naa.
Yatọ si Ọlajide, wọn tun fi oju Wẹmimọ Adeyanju, t'oun si n kẹkọọ l'ọwọ n'ile ẹkọ gbogboniṣe kan la gbọ pe oun pẹlu jọ n ṣiṣẹ jibiti naa.
Agbegbe Apẹtẹ n'ilu Ibadan la gbọ pe ọwọ ti tẹ Adeyanju.
Ọlajide n'igba to n jẹwo bo ṣe n lu jibiti naa sọ pe oun yoo gba akanti ati orukọ ẹni t'oun ba a fẹ ra ọja l'ọwọ ẹ, toun yoo si fi ayederu owo ranṣẹ si iru ẹni bẹẹ. O l'ẹni naa yoo ri owo l'ori foonu ẹ, ṣugbọn ti owo naa ko wọle.
O jẹ ko di mimọ pe ẹẹmẹta pere l'oun ṣe e ko to di pe aṣiri oun tu, t'ọwọ si tẹ oun. O ni obinrin kan to da oun mọ lo tu aṣiri oun sita, ko to di pe ọwọ palaba oun segi.
Adeyanju ninu ọrọ rẹ sọ pe Ọlajide loun maa n tẹle l'ẹyin lọ ọ lu jibiti ni, ẹni to sọ pe ẹẹkan ṣoṣo l'oun ṣi lu jibiti yii.
No comments:
Post a Comment