Oloye Rotimi Olumọ, to jẹ alakoso f'ẹgbẹ Oodua People's Congress ( OPC), ti igun Ọtunba Gani Adams, ti ke si awọn ọba alaye ilẹ Yoruba lati b'awọn da si ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn mẹta to wa ni atimọle l'ori ọrọ Wakili, ti wọn mu lori ẹsun ijinigbe n'ijọba ibilẹ Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.
Ọkunrin naa lo sọrọ yii lakooko to n b'awọn akọroyin sọrọ niluu Ibadan, O sọ pe ki i ṣe ẹṣẹ f'ọmọ ẹgbẹ OPC lati daboobo wọn n'ilẹ Yoruba, ati pe lara nnkan ti idasilẹ ẹgbẹ yii wa fun ni, to si l'awọn ko si le maa wo k'awọn gba awọn Fulani laaye lati gba ilẹ wọn mọ wọn lọwọ.
Olumọ, wa rọ gbogbo awọn ọba ilẹ Yoruba lati lo gbogbo ọna ti wọn ba mọ lati ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn yii jade ninu ahamọ ti wọn wa.
O ni iyawo ọkan lara awọn eeyan yii wa ni ọsibitu UCH, nibi to ti n gba itọju nitori ko ri ọkọ ẹ.
Alakoso awọn OPC nipinlẹ Ọyọ naa tun sọ pe o yẹ ki wọn dupẹ gidi lọwọ Aarẹ ọna kankanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams fun bo ṣe n jẹ ki alaafia jọba nilẹ Yoruba.
O ni nnkan tawọn n fẹ bayii ni atilẹyin awọn eeyan lati ri i pe aabo to peye wa kaakiri ilẹ naa.
Bẹẹ lo ni awọn fẹ ki ijọba ipinlẹ Ọyọ mọ daju pe gbogbo ọna l'awọn OPC n wa lati ri i pe ijinigbe n'ipinlẹ naa di afi sẹyin, nitori awọn fẹ ki alaafia jọba.
Bakan naa ni wọn tun rọ Alaafin tiluu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, Ṣọun Ogbomọṣọ, Olubadan tiluu Ibadan, Ọọni Ile-Ifẹ atawọn ọba alaye yooku lati ma ṣe jẹ ki awọn eeyan wọnyii ku sinu ahamọ ti wọn fi wọn si.
O ni nnkan to jẹ awọn logun ju bayii ni itusulẹ awọn eeyan yii.
No comments:
Post a Comment