Eré ìdárayá tún gb'ọ̀nà àrà yọ ní Kwara, ìjọba fẹ́ẹ́ ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 20, 2021

Eré ìdárayá tún gb'ọ̀nà àrà yọ ní Kwara, ìjọba fẹ́ẹ́ ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára


Bi ere idara awọn ile ẹkọ kaakiri ipinlẹ Kwara ṣe bẹrẹ, ijọba ipinlẹ naa ti ṣe ileri wi pe awọn yoo bẹrẹ si i lo ere idaraya lati maa fi ro gbogbo awọn ọdọ ipinlẹ naa l'agbara.

Igbakeji gomina, Kayọde Alabi lo sọrọ naa di mímọ lanaa ti í ṣe Wẹsidee nibi ifigagbaga ere idaraya láwọn ileewe nipinlẹ naa, eyi ti wọn pe ni Kwara School Football Challenge Competition ti Kwara Football Academy ṣagbatẹru rẹ.

Níbẹ lo ti sọ pe ere idaraya lasiko yii n pese jijẹ mimu sori tabili f'awọn to ba mọ ipa rẹ.

O ni eto ifigagbaga naa yoo tun jẹ anfaani nla f'awọn ileewe, paapaa àwọn akẹkọọ lati wa ni iṣọkan, ti yoo si tun jẹ ki wọn mọ awọn to ni ẹbun ere idaraya ninu awọn akopa.

Ṣaaju asiko yii ni akọwe agba lẹka Ileeṣẹ to n ri sọrọ ere idaraya ati ọdọ nipinlẹ naa, Amofin Funkẹ Banirẹ ti gbe oriyin f'awọn to ṣagbatẹru ifigagbaga naa.
 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI