Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ tuntun lamọran wi pe ki wọn ri i daju pe iṣẹ ti wọn gbe le wọn l'ọwọ ni wọn gb'ajumọ, dipo ki wọn maa wo ariwo ọja, eyi ti ko kan wọn.
Ana ti i ṣe Tusidee ni Gomina AbdulRazaq ti s'ọrọ yii l'asiko to n bura f'awọn kọmiṣanna tuntun mẹwaa ati oludamọran pakaki kan to ṣẹṣẹ yan s'inu ijọba rẹ lati ba a ṣiṣẹ papọ.
O ni wọn gbọdọ maa mu awọn ayipada rere ti yoo gbe orukọ wọn ati ipinlẹ naa ga l'oju araye, ati pe ki wọn f'ọwọsowọpọ lati ṣiṣẹ papọ fun idagbasoke ipinlẹ naa.
Lara awọn kọmiṣanna to bura fun naa ni: Senior Ibrahim Suleiman (Tertiary Education); Arinola Fatimoh Lawal (Enterprise); Aliyu Kora Sabo (Energy); Aliyu Mohammed Saifudeen (Local Government and Chieftaincy Affairs); Suleiman Rotimi Iliasu (Works and Transport); Mariam Ahmed Hassana (Special Duties); ati Raji Razaq (Health).
Awọn yooku ni: Wahab Femi Agbaje (Water Resources); Remilekun Oluwatobi Banigbe (Environment); ati Deborah Aremu (Women Affairs and Social Development).
Bakan naa lo tun bura fun Mallam Attahiru Ibrahim gẹgẹ bi oludamọran pataki f'ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya.
No comments:
Post a Comment