Ko ti i sẹnmi to le sọ pato iru iku to pa gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Chika Uba l'ọjọ Aiku, iyẹn Sande ọsẹ to kọja lọ l'ọhun, to si n jẹ iyalẹnu pe ọkunrin naa le ku lai ṣaisan.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni bọọlu ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Leicester ni Chika ati ọrẹbinrin rẹ, Amaka Joseph lọ ọ wo n'ile igba Runway to wa ni l'agbegbe Adeniyi Jones, ijọba ibilẹ Ikẹja, l'Ekoo l'ọjọ.
Igba to fẹẹ lọ ọ wo bọọlu naa lo ya lọ ọ gbe Amaka n'ile rẹ lati jọ lọ. Bi wọn si ṣe wo bọọlu naa tan la gbọ pe Chika tun tẹle Amaka pada síle wọn.
Bi wọn ṣe n wọle Amaka la gbọ pe Chike bẹrẹ si i ṣe gan-gan-gan, to si jẹ iyalẹnu fun ọrẹbinrin rẹ yii. L'oju ẹsẹ ni wọn sọ pe Amaka ti sare lọ ọ pe awọn alabagbe rẹ lati wa a ba oun wo nnkan to ṣe Chika.
Bi wọn ṣe ri nnkan to n ṣẹlẹ yii ni wọn lo o mu wọn pinnu lati sare gbe e lọ si ọsibitu to wa nitosi, ṣugbọn ti wọn lo o ṣeni laaanu wi pe oju ọna ni Chika ku si.
Ọsibitu naa ni wọn ti pada sọ pe oku Chika ni wọn gbe wa f'awọn. Pẹlu ibanujẹ ọkan la gbọ pe Amaka fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si l'awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii l'ori ẹ.
Olumuyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko f'idi iṣẹlẹ naa mule, oun si lo jẹ ka mọ pe iwadii wọn ṣi nlọ lọwọ lati mọ iru iku to pa Chika.
No comments:
Post a Comment