Barcelona tu aṣiri idi ti wọn fi gba ọọmi ayo pẹlu Levante l'anaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 12, 2021

Barcelona tu aṣiri idi ti wọn fi gba ọọmi ayo pẹlu Levante l'anaa


Akọni-mọ-n-gba ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Ronald Koeman tu aṣiri nla to wa n'idi bi wọn ṣe gba aami ayo mẹta-mẹta pẹlu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Levante ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye l'alẹ ana ti i ṣe Tusidee.
 
Barcelona lo n lewaju pẹlu aami ayo mẹta ninu ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa, ṣugbọn gbara ti wọn wọle ipele keji l'awọn Levante naa da a aami ayo mẹta naa pada fun wọn, to si jẹ pe ọọmi ni ifẹsẹwọnsẹ naa pari si.

Lionel Messi ati Pedri ni wọn gba aami ayo naa wọle l'aaarin iṣẹju marundinlogoji ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa, ṣugbọn ti Gonzalo Melero, Jose Luis Morales ati Ousmane Dembele naa da a pada fun wọn.
 
N'igba to n s'ọrọ, Koeman sọ pe “Bi ẹ ba n wo ifẹsẹwọnsẹ naa ni ipele akọkọ, a n ṣe daadaa, orin to dun ni bọọlu naa n kọ jade, ati ipinnu lati bori. A ṣiṣẹ lati tete gba aami ayo meji wọle."
 
O ni ṣe ni nnkan yi pada b'awọn ṣe wọle ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa, to si ṣoro fun wọn lati tubọ maa ṣe daadaa lati le bori idije naa, to si lo o ṣe ni laaanu pe agbara t'awọn fi bẹrẹ dinku si nnkan t'awọn lero, to fi jẹ ọọmi l'awọn pada yọri ẹ si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI