Aye o! Ṣọọṣi sẹlẹ kan l'Ekoo ni gbajumọ oniṣowo l'Ogun n lọ ko to poora l'oju ọna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 12, 2021

Aye o! Ṣọọṣi sẹlẹ kan l'Ekoo ni gbajumọ oniṣowo l'Ogun n lọ ko to poora l'oju ọna


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
 
Bo tilẹ jẹ pe titi d'asiko ta a pari iroyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi n ṣe ileri wi pe awọn yoo mọ ibi ti gbajugbaja oniṣowo kan n'ipinlẹ Ogun, Arabinrin Sarah Dosekun wọlẹ si, sibẹ inu idaamu ati iporuru ọkan l'awọn mọlẹbi rẹ wa.
 
Iṣọ oru ti wọn lo o fẹẹ waye ninu ṣọọṣi sẹlẹ kan ti wọn pe ni Celestial Church of Christ, Calvary Parish 1 to wa l'agbegbe Ọgba n'ilu Eko la gbọ pe Sarah, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin naa n lọ ko to o poora.
 
Ko ti i sẹni to le sọ ibi ti Sarah wa titi d'asiko ta a pari iroyin yii.

AWIKONKO gbọ pe Agbegbe Mowe ni Sarah ti wọ mọto bọọsi l'Ọjọbo-Tọsidee ọsẹ to kọja, to si jẹ pe n'igba ti wọn maa fi de agbegbe Aṣeeṣe l'opopona marosẹ Eko si Ibadan ni wọn ko ti gburo rẹ mọ.
 
Ọkan l'ara awọn ọmọ obinrin naa, Janet n'igba to n s'ọrọ sọ pe nnkan bi aago meje kọja iṣẹju mẹẹdogun ni mama naa kuro n'ile, to si l'oun n lọ si iṣọ oru. O n'igba ti mama oun de agbegbe Aṣeeṣe ni wọn pe oun lati fi to oun l'eti.
 
Ko pẹ si asiko yii la gbọ pe wọn tun pe mama yii lati mọ ibi to de, ṣugbọn ti ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ mọ. T'ilẹ ọjọ naa fi ṣu ni wọn ko gburo mama yii, eyi ti wọn sọ ki i ri bẹẹ tẹlẹ.
 

Aarọ ọjọ keji la gbọ pe wọn tun bẹrẹ si i pe mama naa, ṣugbọn ti nọmba rẹ ko tun lọ. Eyi lo jẹ ki wọn fura pe nnkan n ṣẹlẹ. L'oju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti gba teṣan ọlọpaa Mowe lọ lati lọ fi to wọn leti.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n'igba ton f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe loootọ ni, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ ibi ti mama naa wọlẹ si, ti wọn si l'awọn n'igbagbọ pe awọm yoo ri mama yii laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI