"Ẹ ṣ'aanu mi, ẹ da aṣọ aṣiri bo mi" lọrọ ẹbẹ to n tẹnu gendekunrin kan ti ọjọ ori ẹ ko ti ì ju ọdún mẹtalelogun lọ, Saheed Adeniran, ìyẹn akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekiti ti wọn lo o fẹẹ fi ọrẹ rẹ ṣ'owo jade.
Laipẹ yii ni fọ́nrán ibi ti aṣiri Saheed ti tu, ìyẹn lasiko to fẹẹ bẹrẹ sí í pogede lati fi ọrẹ rẹ timọtimọ, ti wọn jọ n gbe inu yara kan náà ṣ'oogun owo.
Awọn kan la gbọ pé wọn n gbọ bi Saheed ṣe n p'ọfọ, to sì n da'rukọ ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gbe.
Saheed gbe igba kan to kún fún oògùn abẹnu-gọngọ dani, pẹlu Ado ati aṣọ ti wọn lo o jẹ ti ọrẹ rẹ.
Ibi to ti n p'ọfọ náà la gbọ pé wọn ti Sare wọlé tọ ọ lọ, ti wọn si bá àwọn igba naa lọwọ ẹ.
Ṣe ni wọn dáná iya fún un Saheed, akẹkọọ Ekiti State University (EKSU) naa ko to di pe wọn wọ ọ sita lati fi ṣẹlẹya, to sì n bẹbẹ pé kí wọn foju aanu wo oun.
Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pé wọn gbà wọn lamọran lati lọ fa Saheed lé àwọn ọlọpaa lọwọ.
Fọ́nrán náà ree:
No comments:
Post a Comment