Awọn ara agbegbe Idi-Ọgẹdẹ gbe oṣuba kare fun gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 3, 2021

Awọn ara agbegbe Idi-Ọgẹdẹ gbe oṣuba kare fun gomina AbdulRazaq


Gbogbo awọn ara agbegbe Idi Ọgẹdẹ to wa n'ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti wọn ti n gbe oṣuba rabandẹ-rabandẹ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'ori bo ṣe pari opopona to gba agbegbe naa kọja fun wọn.

Bakan naa n'ijọba ipinlẹ naa tun wa a ṣe ileri wi pe awọn yoo tubọ maa ṣe awọn nnkan ti yoo maa mu ayẹ dẹrun f'awọn araalu nigba gbogbo, tori pe igbe aye irọrun lo jẹ oun l'ogun.

Lonii ni Gomina AbdulRazaq fi ileri naa lelẹ l'asiko to n ba gbogbo awọn ara agbegbe Idi-Ọgẹdẹ yii ṣe ipade, to si tun ṣe ileri wi pe ijọba oun ko ni ṣai ṣe awọn nnkan to yẹ f'awọn araalu lati jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.

N'igba to n sọrọ, AbdulRazaq ti igbakeji re, Ọgbẹni Kayọde Alabi ṣ'oju fun jẹ ko di mimọ pe idagbasoke awọn agbegbe ati igberiko lo jẹ ijọba AbdulRazaq l'ogun, ti ko si ni da'wọ rẹ duro ti ijọba naa yoo fi kasẹ nilẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI