Bọsun Ọlaniyi, Abẹ́òkúta:
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti r'ọwọ to baba arúgbó ẹni ọdún mejilelaadọta kan, Káyọ̀dé Adéníyì ti wọn lo o f'ipa ko ibasun f'ọmọ ọdún mẹwàá l'agbegbe Ijoko, ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bá a ṣe gbọ, wọn ni Káyọ̀dé to n gbe l'ojule kejila, àdúgbò Abẹ́rẹ́ Ifá, Ijoko ki ọmọ ọdún mẹwàá ta a fi orúkọ bo l'aṣiri naa, o sí kó ibasun fún un karakara.
Wọn ni ṣe ni ọmọ náà lọ béèrè lọwọ Káyọ̀dé bóyá òun lo ba wọn ká aṣọ tí wọn sa sita, ṣugbọn kaka ki Káyọ̀dé sọ f'ọmọ naa pe oun ko ka aṣọ, wọn ni ṣe lo wọ ọ wọnú yàrá, to ko ibasun fún un.
Ki ọmọ yii ma ba a pariwo, wọn ni ṣe ni Káyọ̀dé fi irọri (pillow) bo ọmọ náà lẹnu lásìkò tó n ba a laṣepọ.
Ṣe la gbọ pé ọmọ yii sunkun lọ bá ẹgbọn rẹ nile, to sì ṣàlàyé bi Káyọ̀dé ṣe bá a laṣepọ. Loju ẹsẹ ni wọn ti gba teṣan ọlọpaa lọ láti fi to wọn létí, ti wọn sì lẹsẹkẹsẹ láwọn ọlọpaa ti lọ ọ gbe e.
Káyọ̀dé nigba toun naa n sọrọ sọ pé lóòótọ́ ni, ati pe ọbẹ loun yọ s'ọmọ naa lati fi d'ẹru ba a. Bakan naa lo sọ pé òun tun n ko ibasun f'awọn ọmọ òun mẹta ti wọn ṣì kéré.
Ọgá ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti pàṣẹ pé kí ìwádìí tubọ tẹ síwájú.
No comments:
Post a Comment