Ọkan lara awọn agbabọọlu to n gba aarin fun ikọ ẹgbẹ agbọọlu Super Eagles ti Naijria, Raheem Lawal ti sọ pe igbakeji akọnimọngba Super Eagles tẹlẹri, Daniel Amọkachi ni ko f'oun laaye lati kopa ninu idije bọọlu ilẹ adulawọ, iyẹn African Cup of Nations ti wọn gba l'ọrilẹ-ede South Africa l'ọdun 2013.
Lawal to n gba bọọlu fun ẹgbẹ Akhisarspor ti orilẹ-ede Turkey lo sọrọ naa l'ori ikanni ayelujara ti Instagiraamu laipẹ yii, to si ni Ikẹ Ṣorunmu to n d'ile mu fun Super Eagles naa pẹlu awọn to ṣe atako oun pẹlu bo ṣe jẹ pe adugbo kan naa l'awọn jọ n gbe ni Mushin, ipinlẹ Eko tẹlẹ.
O ni Amọkachi mọ ọn mọ yọ orukọ oun kuro ninu awọn ti yoo kopa l'ọdun naa tori to ni ẹnikan to fẹ ki irawọ rẹ tete yọ.
Bẹ o ba gbagbe, Lawal ni wọn mu l'ọdun pẹlu awọn meji mi in, iyẹn Nosa Igiebor ati Obiọra Nwankwo in n'igba ti wọn mu n'igba ti wọn lọ gba idije CAF U-23 l'ọdun 2011.
Bẹ o ba gbagbe, Lawal ni wọn mu l'ọdun pẹlu awọn meji mi in, iyẹn Nosa Igiebor ati Obiọra Nwankwo in n'igba ti wọn mu n'igba ti wọn lọ gba idije CAF U-23 l'ọdun 2011.
No comments:
Post a Comment