Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa iwọde ifẹhonuhan ti olori ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyẹmo, iyẹn Igboho wa a ṣe n'ipinlẹ naa, to si l'awọn to n ṣe ipolongo lati gba ominira ilẹ Yoruba kan n ṣe lapo ara wọn ni, oun ko fọwọ si i.
Laipẹ yii ni Igboho wọlu Akurẹ lati lọ ọ ṣe ifẹhonuhan alaafia lati gba ominira fun ilẹ Yoruba, ki gbogbo ọmọ Oduduwa le bọ kuro l'ọwọ awọn ijọba ti wọn pe ni Amunisin labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.
Nibi iwọde ifẹhonuhan naa ni Igboho ti sọ pe Gomina Akeredolu mọ nipa b'awọn ṣe wa s'ipinlẹ aa, ati pe digbi lo wa l'ẹyin awọn nipa idaduro ilẹ Yoruba kuro lara Naijiria.
Ṣugbọn Akeredolu n'igba to n tako ọrọ naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ti gbọ nipa wi pe Igboho fẹ wa a ṣe ifẹhonuhan alaafia, to si l'oun ko le da ifẹhonuhan naa duro ori pe onikaluku lo lẹtọọ labẹ ofin lati fẹhonu han, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe oun f'ọwọ si ariwo ti wọn n pa l'ori iyapa Yoruba kuro lara Naijiria.
No comments:
Post a Comment