Lonii ni Ọlọfa t'ilu Ọffa, Ọba Muhammed Mufutau Gbadamọsi, Eṣuwoye keji n ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun mọkanla l'ori ipo, ti Ọba Ahmed Awuni Babalọla, Arepo kẹta naa si n ṣayẹyẹ ọdun mejilelọgbọn l'ori ipo pẹlu ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkanlelaadọrun-un l'oke eepẹ.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n'igba to n b'awọn Ọba alaye naa ṣ'ajọyọ ṣapejuwe wọn gẹgẹ awọn ọba to n gba alaafia l'aaye, to si ni asiko wọn ti mu idagbasoke ti ko l'ẹlẹgbẹ wọ ipinlẹ naa.
Bẹẹ lo gb'adura ẹmi gigun ati alaafia fun wọn.
No comments:
Post a Comment