Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'ọjọ Ẹti-Furaidee ana ti ba gbogbo awọn agbaagba ninu ẹsin Isilaamu ṣinu aawẹ Ramadaani, l'ojuna lati fi ẹmi imoore han si wọn.
Ana ti i ṣe Furaidee ni ọjọ Ẹti to gb'ẹyin ninu aawẹ Ramadaani to n lọ l'ọwọ yii, eyi ti yoo pari l'ọsẹ tuntun ta a ṣẹṣẹ wọnu rẹ yii.
A gbọ pe b'awọn ẹlẹsin musulumi e wa nibẹ naa l'awọn ẹlẹsin kristẹẹni naa pọ nibẹ pẹlu lati jọ jẹ, ti wọn si tun jọ mu.
L'ara awọn to wa n'ibẹ ni: Igbakeji gomina, Kayọde Alabi; abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Danladi; alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Alaaji Abdullahi Samari; Ọnọrebu Ọlawọyin Magaji; akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril ati aṣoju Naijiria s'ilẹ Malaysia, Amb. Nurudeen Mohammed.
Awọn mi in ni: Sẹnetọ Ahmed Mohanmed; Sẹnetọ Sulaiman Ajadi; Sẹnetọ Simeon Ajibọla; Oloye James Ayeni; Alaaji Kunle Sulyman; Oloye Rex Ọlawọye; Alaaji LAK Jimoh; Alaaji Abubakar Ndakene; Alaaji Shogo; Alaaji Mayaki ati Alaaji Baba Podo.
Bakan naa l'awọn bi i Oloriewe Raheem Adedoyin, Alaaji Alhassan Bagudu, Ọmọwe Mohammed Ghali, Ọjọgbọn Shehu Adaramaja, Ọnọrebu Abdulmumini Katibi ati Alaaji Ganiyu Galadima ko gbẹyin nibẹ.
No comments:
Post a Comment