Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii apapọ awọn oṣiṣẹ orilẹ-ede yii ti sọ pe awọn yoo da iṣẹ silẹ bi Gomina ipinlẹ ipinlẹ Kaduna, Malaamu Nasir El-Rufai ba ṣi duro lori ipinnu rẹ lati da awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa silẹ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari, eyi ti wọn pe akọle ẹ ni 'Tete pe Gomina El-Rufai s'akiyesi' ("Call Governor El-Rufai to order") 'ọjọ Mọnde ana ni Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Ayuba Wabba ti sọrọ yii jade.
Laipẹ yii ni Gomina El-Rufai kede wi pe oun fẹẹ din awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa ku, pẹlu erongba lati le ṣe awọn ohun am'ayedẹrun s'aarin ilu, to si ni owo oṣu t'oun n san f'awọn oṣiṣẹ ti pọ ju agbara ipinlẹ naa lọ.
El-Rufai l'oun yoo ran awọn ti ijọba oun ba da duro lọwọ l'ẹka eto iṣẹ agbẹ ati iṣẹ ọwọ t'onikaluku wọn ba yan laayo.
Ayuba Wabba ninu atẹjade naa lo ti sọ pe El-Rufai ko l'aṣẹ lati gbe igbesẹ naa, to si ni ko ba ilana ati ofin oṣiṣẹ mu.
O ni iwe ofin ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ sọ koko pataki ti ijọba fi le da oṣiṣẹ duro, eyi to ni ko si eyikeni ninu erongba El-Rufai nibẹ rara. O lo pọn dandan ki ijọba fi to ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ leti ko to le gbe igbesẹ naa.
Siwaju si i lo sọ pe El-Rufai ko fi ọrọ igbesẹ to fẹẹ gbe to igbimọ ẹgbẹ oṣiṣẹ leti lati jọ sọ asọyepọ, eyi to l'awọn ko ni i fara mọ ọn.
No comments:
Post a Comment