Asiko yii ki i ṣe asiko idunnu rara fun gbogbo awọn ọlọja oju popona to wa nitosi ọja kan ti wọn n pe ni ọja Wurukum to wa nilu Makurdi, ipinlẹ Benue, pẹlu bi ijọba ipinlẹ naa ṣe loun ko fẹẹ ri wọn mọ rara.
Yatọ si awọn ọlọja oju popona ọja yii, ijọba ipinlẹ naa tun sọ pe gbogbo awọn to n lo ṣọọbu ninu ọja Wurukum to wa loju ọna Swange Cinema l'awọn ko fẹẹ ri mọ.
O lẹni ti ko ba tẹle aṣẹ ijọba ni yoo f'oju finna ofin, tori pe ijọba ti ṣetan lati wo awọn ṣọọbu ninu ọja naa.
Awọn igbimọ ipinlẹ naa, iyẹn Benue State Executive Council ni wọn gbe aṣẹ yii kanlẹ, ti wọn si l'awọn ọlọja ti ko ba kuro ni wọn yoo gba ọja wọn, ti wọn ko si ni i ri awọn ọja naa gba pada mọ, ati pe awọn to n lo ṣọọbu nibẹ naa bi wọn ko ba kuro ni ijọba ṣetan lati wo awọn ṣọọbu naa danu.
Kọmiṣanna f'eto Iroyin, Aṣa ati Irin Ajo Afẹ, Ọnọrebu Ngunan Addingi l'asiko to n b'awọn akọroyin sọrọ sọ pe gbogbo awọn t'ọrọ kan yii l'awọn ti pese aaye mi in silẹ fun wọn ninu ọja igbalode ti Makurdi, iyẹn Makurdi International Market, nibi to sọ pe ṣọọbu ti ṣi silẹ loriṣiriṣi.
No comments:
Post a Comment