Gomina Babajide Sanwo-Olu t'ipinlẹ Eko ti sọ pe ipinlẹ naa ko nilo Amọtẹkun fun eto aabo, to si jẹ ko di mimọ pe iṣẹ t'awọn Amọtẹkun fẹẹ ṣe l'oun ti gbe kalẹ tipẹ.
Sanwo-Olu lo s'ọrọ yii l'ọjọ Aiku ti i ṣe Sande ijẹta l'ori tẹlifiṣan n'ipinlẹ Eko, nibẹ lo ti sọ pe ṣaaju ki wọn to o bẹrẹ si i m'ẹnuba ọrọ Amọtẹkun l'awọn ti da ileeṣẹ eleto aabo agbegbe kan to pe ni Neighbourhood Safety Corps silẹ, to si ni iṣẹ ti Amọtẹkun fẹẹ ṣe l'awọn ti n ṣe.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe orukọ l'asan lo yi pada si nnkan t'awọn ti da silẹ tẹlẹ l'Ekoo, ẹni to l'oun gbe oṣuba kare f'awọn Gomina Yoruba to ku lori nnkan t'awọn naa n ṣe, paapaa l'ori ọwọ to ni wọn fi mu ọrọ eto aabo.
“Ẹgbẹrun meje l'awọn to n ṣiṣẹ nileeṣẹ eto aabo Neigbourhood to n ṣiṣẹ l'Ekoo, iṣẹ ti Amọtẹkun n ṣe l'awọn naa n ṣe, ko si iyatọ. Awọn ẹnu ibode wa ni gbogbo wọn, ti wọn n ta wa l'olobo, ti wọn si tun n woye awọn nnkan to n lọ kaakiri.
"Awon ni wọn n jẹ ka mọ bo ṣe n lọ l'awọn igberiko kaakiri. Nnkan to yatọ ninu ọrọ ti wọn ni pe wọn ko le gbe ibọn tabi nnkan ija ogun dani lati fi ṣiṣẹ."
No comments:
Post a Comment