Ọpẹ o! Ọwọ Amọtẹkun, OPC ati Fijilante tẹ ogbologbo ajinigbe mẹfa l'Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 29, 2021

Ọpẹ o! Ọwọ Amọtẹkun, OPC ati Fijilante tẹ ogbologbo ajinigbe mẹfa l'Ọyọ


Orin ọpẹ la gbọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eleto aabọ ilẹ Yoruba, Amọtẹkun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC ati Vigilante Group of Nigeria, VGN mu s'ẹnu laaarọ oni ti i ṣe Tọsidee n'igba t'ọwọ wọn tẹ awọn ogbologbo ajinigbe ti ko din ni mẹfa ọtọọtọ.
 
Ni nnkan bi aago mẹrin aarọ oni la gbọ pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa l'oju ọna Okeho si Ilua ati Okeho si Isẹyin n'ijọba ibilẹ Kajọla, ipinlẹ Ọyọ.
 
 
Ki i ṣe ahesọ wi pe awọn ajinigbe pọ l'ọna yii, ti wọn si ti kolonka awọn eeyan gbe lati gba owo l'ọwọ wọn, bẹẹ si ni wọn tun ti fi ọpọ ẹmi awọn eeyan ṣ'ofo danu.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe l'awọn ileeṣẹ eleto aabo to sunmọ awọn araalu daadaa yii panupọ lati gbogun ti awọn ọdaran l'oju ọna naa, ta a si gbọ pe ṣe ni wọn pin ara wọn s'ọna meji lati ṣiṣẹ yii.
 
 
Yatọ si awọn t'ọwọ tẹ yii, a tun gbọ pe ọwọ tun tẹ awọn marun-un mi in n'ijọba ibilẹ Ṣaki l'aaarọ oni kan naa.
 
Olori awọn Amọtẹkun n'ipinlẹ Ọyọ, Ọlayinka Ọlayanju to gbe iroyin naa sita jẹ ko ye wa pe asiko t'awọn ọdaran naa lọ ọ da'na l'awọn oṣiṣẹ wọn lọ koju wọn, ti wọn si ba wọn sọ'ya ija, ṣugbọn to ni ọwọ pada tẹ l'ara wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe Auwalu Atine, Ibrahim Abu, Shuaib Balau, Ibrahim Musa, Abdullah Masika ati Umar Aliu Masika l'ọrukọ awọn t'ọwọ tẹ naa, ta a si gbọ pe ẹya Fulani ni gbogbo wọn.
 
 
Ọlayanju sọ pe awọn ṣi n wa awọn yooku to na papa bora l'asiko t'ọwọ tẹ awọn wọnyii
 
Bakan naa lo tun jẹ ko ye wa pe awọn tun gba maluu 183, oriṣiriṣi nnkan ija oloro ati owo ti ko din l'ẹgbẹrun lọna igba at'aabọ, iyẹn N268,470 l'ọwọ wọn.
 
 
O wa fi ye wa pe awọn ti fa awọn t'ọwọ tẹ naa le awọn ọlọpaa l'ọwọ fun iwadii s'iwaju si i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI