Ọpẹ o! Ipinlẹ Kwara jeere obitibiti owo l'oṣu mẹta akọkọ ọdun 2021 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 20, 2021

Ọpẹ o! Ipinlẹ Kwara jeere obitibiti owo l'oṣu mẹta akọkọ ọdun 2021


Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ipawo-wọle n'ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Internal Revenue Service (KW-IRS) ti kede l'aarọ oni ti i ṣe Tusidee wi pe awọn ti jeere biliọnu mẹsan-an ataabọ naira l'aaarin oṣu mẹta akọkọ ọdun 2021 ti a wa yii.
 
Wọn ṣalaye s'iwaju pe owo ti ko din ni N9,598,504,939.90kọbọ l'awọn pa wọle fun ijọba ipinlẹ naa, eyi to fi han wi pe ipinlẹ naa ti n gun oke agba n'ibi eto ipawo-wọle, to si ni eto ọna t'awọn gba ko ṣẹyin b'awọn ṣe eto imọ ẹrọ igbalode, ati lati di gbogbo ibi ti owo ti n sọnu lẹka eto ipawo-wọle.
 
A gbọ pe latigba ti wọn ti da ẹka ileeṣẹ yii silẹ l'ọdun 2016, akọkọ ree ti wọn yoo maa jeere to to eyi, eyi to fi han daju pe ipinlẹ naa ti n dagba soke gidi.
 
N'igba to n b'awọn akọroyin sọrọ n'ilu Ilọrin. Arabinrin Ṣade Ọmọniyi to jẹ alaga ileeṣẹ eto ipawo-wọle n'ipinlẹ naa sọ pe ọdun to kọja lo yẹ k'awọn ti bẹrẹ si i jeere gidi, ṣugbọn to jẹ ipalara naa waye latari ajakalẹ arun Korona (Covid-19) to wọ orilẹ-ede yii.
 
O ni eyi lo jẹ k'ijọba gb'oju fo owo ori awọn ileeṣẹ fo da, tori pe ajakalẹ arun naa d'oju eto ọrọ aje bolẹ gidigidi.
 
Siwaju si i lo sọ pe agbeyẹwo ati gbigba owo ori s'apo ijọba l'ẹka KW-IRS at'awọn ileeṣẹ to pe ni MDA l'awọn n ṣe loore-koore. O ni diẹdiẹ l'awọn owo yii n wọle tẹlẹ. O ni latigba ti wọn ti bẹrẹ iṣẹ l'oṣu kẹwaa ọdun 2019, ileeṣẹ naa ti bẹrẹ si i ṣiṣẹ l'ọsan ati l'oru lai sinmi.
 
Awọn akitiyan yii lo sọ pe wọn so eso rere, to si l'awọn jeere biliọnu mẹtalelogun n'igba ti yoo fi di ọgbọn ọjọ oṣu kẹsan-an, ati pe owo naa wọ biliọnu mọkanlelọgbọn din diẹ (N30.7b) naira n'ipari ọdun 2019.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI