O tan! Ile-ẹjọ Tribuna yẹyẹ Jẹgẹdẹ, wọn l'ẹsun to gbe wa ko kun oju oṣuwọn to - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 20, 2021

O tan! Ile-ẹjọ Tribuna yẹyẹ Jẹgẹdẹ, wọn l'ẹsun to gbe wa ko kun oju oṣuwọn to


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun to n gbọ ẹjọ awọn oludije s'ipo l'orilẹ-ede yii, iyẹn Tribunal ti da ẹjọ ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Ọgbẹni Eyitayọ Jẹgẹdẹ pe lati tako idibo to gbe Gomina ipinlẹ Ondo Arakunrin Rotimi Akeredolu wọle l'ẹẹkeji.
 
Oludije s'ipo Gomina Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ninu idibo to waye l'ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020, nibi ti Akeredolu ti jawe olubori.
 
L'ẹyin ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission kede Akeredolu lati inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo naa ni Eyitayọ Jẹgẹdẹ gba ile ẹjọ naa lọ wi pe ki wọn da idibo naa nu, tori to lo o kun fun oriṣiriṣi awuruju.
 
Ori ẹrọ alatagbata ti Zoom ni idajọ naa ti waye lonii, nibi t'awọn igbimọ idajọ ẹlẹni mẹta naa ti Onidajọ Umar Abubakar lewaju rẹ ni wọn ti sọ pe ẹsun ti wọn gbe wa s'iwaju awọn ko kun oju oṣuwọn to, ati pe awọn ẹri ti wọn gbe wa ko ṣe e tẹwọ gba.
 
L'oju ẹsẹ ni wọn ti da ẹjọ naa nu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI