MI o wa ìyàwó lori ikanni ayelujara o - Oluwo pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 29, 2021

MI o wa ìyàwó lori ikanni ayelujara o - Oluwo pariwo sita



Oluwo tilu Iwo, Ọba AbdulRasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni ti sọ pe k'ẹnikẹni ma ko b'ọwọb'ọwọ bọ oun l'ọwọ l'ori ọrọ olori ti ko si l'Aafin oun, to si ni ki i ṣe pe oun n wa iyawo tabi olori n'itagbangba.
 
Ki i ṣe pe Oluwo deede pariwo yii sita, ṣugbọn nitori awuyewuye kan ti wọn lo n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara wi pe Ọba AbdulRasheed n lu awọn obinrin kan ni jibiti l'ori ikanni ayelujara, ta a si gbọ pe awọn kan ni wọn n lo orukọ rẹ lati maa fi lu jibiti.
 
A gbọ pe ṣe l'awọn kan ta a ko ti i mọ d'asiko ta a pari iroyin yii lo n fi orukọ Ọba Oluwo lati maa fi beere fun ifẹ awọn obinrin arẹwa l'ọri ayelujara, eyi ti wọn ni Oluwo funra rẹ ko mọ nnkankan nipa rẹ.

Oluwo ninu ọrọ rẹ sọ pe k'ẹnikẹni ma ṣe ko s'ọwọ awọn gbajuẹ tori t'oun ko wa olori tabi iyawo l'ori awọn ikanni ayelujara kaakiri agbaye. O ni iroyin ti to oun leti wi pe awọn kan n lo orukọ oun lati maa fi lu jibiti l'awọn ori ikanni ayelujara.

Siwaju si i lo sọ pe oun ko ni ikanni ayelujara abanid'ọrẹ yatọ eyi eyi t'awọn eeyan yoo nifẹẹ l'ori fesibuuku.
 
O ni gbogbo ẹni to ba gbe ara rẹ silẹ f'awọn onijibiti wa lo jẹ pe afọwọfa ati ojukokoro lo sun wọn debẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI