Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pé ọwọ àwọn ti tẹ awọn mẹrin kan ti wọn ko n'iṣẹ meji ju ki wọn máa fọ ile onile ati ṣọọbu oni ṣọọbu káàkiri lọ.
Ṣọọbu kan ti wọn ti n ta foonu nilu Ile Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun la gbọ pé àwọn mẹrẹẹrin lọ fọ, ko to di pe aṣiri wọn tú sita.
Bi wọn ṣe rí í pe aṣiri awọn ti tu lo mu ki wọn salọ s'ilu Mowe, ipinlẹ Ogun lati farapamọ sí kí owo ma ba a tẹ wọn.
Awọn mẹrẹẹrin náà ni Nura Bashir, ọmọ ogun ọdún; Awalu Aliyu, ọmọ ọdún mejidinlogoji; Shuaibu Abdul Rasheed ọmọ ọdún marundinlọgbọn ati Abdullah Usman toun naa jẹ ọmọ ọdún mẹtalelogun.
Kì í ṣe pé aṣiri awọn èèyàn yìí deede tu, AWIKONKO gbọ pé ọkùnrin kan ti wọn pe Gbenga Ṣiyanbọla lo lọ fi ọrọ awọn mẹrẹẹrin to awọn ọlọpaa leti pe wọn já òun loke.
A gbọ pé ṣe láwọn èèyàn yìí lọ já Gbenga lólè lagbegbe Mowe, ìyẹn lasiko to n tun mọto rẹ tó bajẹ ṣe. Bi wọn se já a lólè tan lo gba teṣan ọlọpaa lọ láti fi to wọn létí.
Ko pẹ rárá tí ọwọ palaba wọn fi segi. Bọwọ ṣe tẹ wọn ni wọn ti n ka boroboro pé ogbologboo adigunjale láwọn n'Ile Ifẹ, ṣugbọn tàwọn sa wa sí ipinlẹ Ogun lati fi arapamọ.
Ọsẹ bi í mélòó kan la gbọ pé ọwọ tẹ ọkan lára wọn nilu Ìkirè, ti wọn sì lóun lo yannanaa bi ọwọ ṣe tẹ awọn yooku rẹ.
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn mẹrẹrin lọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lati tẹsiwaju iwadii lori wọn.
No comments:
Post a Comment