Gómìnà AbdulRazaq kọ orin iṣọkan seti àwọn ọmọ ẹgbẹ APC to n binu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 18, 2021

Gómìnà AbdulRazaq kọ orin iṣọkan seti àwọn ọmọ ẹgbẹ APC to n binu ni Kwara


Orin 'Ija dopin, ogun si tan' láwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara n kọ lásìkò ta a pari iroyin yii pẹlú bi Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ṣe yi sọ pe oun yóò yan lara àwọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn n binu tẹlẹ sinu ìjọba rẹ.

O ti ṣe diẹ ti Gómìnà AbdulRazaq ti tu igbimọ ìṣàkóso rẹ ka lati yan awọn mi in sipo.

Ninu atẹjade kan to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii la ti gbọ pe gbogbo ìpinnu Gómìnà bayii ni lati yan lara àwọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn n binu s'awọn ipo oríṣiríṣi ninu ìṣàkóso rẹ.

Lara awọn wọnyi ni ti awọn ọmọ ẹyìn mínísítà fun eto iroyin, Alaaji Lai Mohammed to fi mọ awọn ọmọ ẹyìn awon agbaagba ẹgbẹ naa ti wọn ko gba ti ijọba Gómìnà AbdulRazaq.

AWIKONKO gbọ pe Gómìnà AbdulRazaq ti ranṣẹ si Alaaji Lai Mohammed lati fi orukọ awọn ọmọ ẹyìn rẹ to bá fẹ ninu ijọba oun ranṣẹ, ki wọn si le tete ṣe àgbéyẹ̀wò wọn ko to o pẹ ju.

Lati yọ ọrọ ẹlẹyamẹya kuro ni igbesẹ ta a gbọ pe Gómìnà AbdulRazaq gbe yii.

Yatọ si Alaaji Lai Mohammed ti AbdulRazaq ranṣẹ si, wọn lo o tun ti ranṣẹ s'awọn agbaagba mi in ninu ẹgbẹ lati fi orukọ awọn ọmọ ẹyìn wọn ti wọn ba fẹ ninu ìṣàkóso rẹ ranṣẹ.

Siwaju si i la gbọ pe lara idi pataki ti Gómìnà AbdulRazaq ṣe tu igbimọ ìṣàkóso rẹ ka ni lati faaye gba àlàáfíà laaye n'ipinlẹ naa nipa fífi àwọn ọmọ ẹyìn Alaaji Lai Mohammed sijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI