Titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan, inu idunnu ati ayọ nla ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara wa lori bi ijọba ipinlẹ naa ṣe yan Ọgbẹni Babatunde Opoọla sinu igbimọ ileeṣẹ to n tẹ iwe iroyin The Herald t'ipinlẹ naa, iyẹn Kwara State Printing and Publishing Corporation, KWPPC.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa gbe jade l'Ọjọru ti i ṣe Wẹsidee anaa, ni wọn ti sọ pe ẹni ti ipo naa tọ si n'ijọba naa, ti wọn si n ki adele olootu iwe iroyin naa tẹlẹ ku oriire ti ipo tuntun yii.
Ọjọ Aiku, iyẹn Sandee to kọja yii n'ijọba kede Opoọla gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ iṣakoso ileeṣẹ iwe iroyin naa.
No comments:
Post a Comment