Iru kileyii lo t’ẹnu awọn eeyan jade l’ọsẹ to kọja yii, to si jẹ pe titi di asiko ta a pari iroyin yii l’awọn eeyan si n beere l’ọwọ ara wọn lati mọ idi ti baale ile ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Akinọla Imọlẹayọ Abayọmi ṣe gbe majele jẹ, ti ko ti i s’ẹni to le dahun rẹ.
Ni nnkan bi aago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ alẹ
Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee ọsẹ to
kọja
yii n’iṣẹlẹ naa
waye l’agbegbe Ago-Oko to wa n’itosi Ṣapọn n’ilu Abẹokuta.
Iyalẹnu nla gba a ni wọn
n’iku Abayọmi i wọn lo o yan iṣẹ awọn to n tẹ iwe (Printing Press) laayo l’agbegbe
Oke-Itoku, Abẹokuta ṣi
n jẹ
n’igba ti wọn
ṣ’akiyesi
pe oogun apẹfọn ati
oogun ekute lo gbe jẹ to fi dagbere f’aye l’ọjọ naa.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO
l’ọwọ
ṣe
sọ,
wọn
ni inu oṣu
to kọja
yii, iyẹn
oṣu
kẹta
ni Abayọmi
ati iyawo ẹ
ja, ti wọn
si ni obinrin naa ko diẹ l’ara awọn ẹru ẹ lati kuro nile
fun Abayọmi.
A gbọ pe ṣe ni
Abayọmi
lu iyawo ẹ
gidi gan-an, to jẹ pe awọn ara
adugbo ni wọn
pada gba obinrin naa silẹ, ko to o di pe o k’ẹru rẹ lọ.
Ko pẹ l’ẹyin ija yii la gbọ pe
Abayọmi
pada lọ
bẹ
iyawo ẹ
ko le pada sile, to si ṣeleri fun un wi pe oun ko ni i luu mọ, ṣugbọn ti wọn ni
obinrin naa loun ko le pada sile naa.
AWIKONKO gbọ pe ko si nnkan meji to
n fa ija l’aaarin Abayọmi ati iyawo ẹ bi ko ju ti iya arugbo
kan ti wọn
l’oun lo ku gẹgẹ bi
iya onile wọn, nitori ti wọn l’ẹni to
n’ile naa ti ku tipẹ, iya arugbo naa la gbọ pe o maa n ba gbogbo awọn
araale ja n’igba gbogbo.
Ọjọ karundinlogbon oṣu kejila ọdun to kọja la gbọ pe mama arugbo yii ti bẹrẹ wahala pẹlu awọn ara ile, paapaa iyawo Abayọmi, ti wọn ni ṣe ni mama arugbo naa maa n ṣ’epe rabandẹ-rabandẹ f’awọn to ba n b’inu si.
Gbogbo akitiyan ti wọn ni Abayọmi ṣe lati
le jẹ
k’iyawo ẹ
pada sile la gbọ
pe o ja si pabo, ti wọn si ni ironu yii pẹlu awon nnkan to je ko
gbe majele jẹ.
Iwadii fi ye wa pe l’aaarọ ọjọ ti
Abayọmi t’ọpọ awọn eeyan tun n pe ni Baba Ibeji maa gbe majele jẹ, wọn ni ṣe lo n
ṣere
bi ẹni to ti mọ pe ọjọ naa loun maa ku ni, ti
ko si fu ẹnikẹni
lara wi pe oun ni ẹdun ọkan
tabi pe oun n palẹmọ iku oun.
Ọmọbinrin
kan ti wọn l’oun pẹlu Baba Ibeji jọ n ṣiṣẹ ni ṣọọbu ni wọn lo o sọ fun pe ko
maa gb’adura f’oun bi ẹmi ba ṣe dari ẹ, ti wọn si ni awada ni wọn n fi ọrọ naa ṣe.
Irọlẹ
ọjọ naa la gbọ pe Abayọmi sọ pe oun ko mọ bi ara ṣe n ṣe oun, t'awọn eeyan si
ni ko maa lọ sile lati lọ tọju ara ẹ.
Asiko
ti wọn lo n lọ s’ile la gbọ pe Abayọmi lọ ọ ra oogun apẹfọn ti wọn n pe ni Sniper pẹlu oogun ekute ti wọn n pe ni Push Out, to fi mo oogun kan naa to wa
ninu igo.
Wọn
ni bo ṣe de’le ni nnkan bi aago meje ọjọ naa lo ki awọn to ba n'iwaju ita, ko
to wọ’le lọ ni tiẹ. Ko pẹ la gbọ pe o bẹrẹ si i po awọn oogun naa papọ, ko to
da a jẹ, iyẹn ni nnkan bi aago mẹjọ si mẹjọ aabọ.
Lẹyin
bi iṣẹju mẹẹdogun ni wọn lo bẹrẹ si i pariwo inu rirun, eyi to mu k'awọn araale
sare yọju si i lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ. Nibi ti wọn ni wọn ti n beere ọrọ l’ọwọ
ẹ lati mọ nnkan to n ṣe e lo ti bẹrẹ si i pọ foomu l'ẹnu.
Eyi
ni wọn lo jẹ k'awọn araale sare pe aburo ẹ lati fi to o leti, ti wọn si tun pe
iyawo ẹ lori foonu lati fi to oun leti. Ibi ti wọn ti n gbiyanju lati mọ nnkan
to ṣẹlẹ ni wọn ti sakiyesi pe awọn oogun ekute ati oogun apẹfọn to da jẹ lo ṣe’ku
pa a.
Baba
agbalagba to gba Abayọmi s’ile ninu ọrọ to b’AWIKONKO sọ lo ti sọ pe ṣe ni wọn
sare wa pe oun nibi t’oun wa wi pe ọkan lara awọn ayalegbe oun ti gbe majele jẹ,
to si l’oju ẹsẹ l’oun ti wa lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni “Eeyan jẹjẹ ti mi o ri ko ba ẹnikẹni fa wahala ni Abayọmi. Ko ti i ju ọdun meji to de inu ile yii. Wọn ni iyawo ẹ to lọ lo jẹ ko pa ara rẹ, ṣugbọn mi o le dahun si i, tori pe mi o si nibẹ.”
Ọkan
l'ara awọn araale naa to ba AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe awọn jọ maa n dapara
ninu ile ni, to si ni ẹyin ferese l'awọn jọ maa n jokoo si l'alẹ lati gb’atẹgun.
N'igba
to n b'AWIKONKO s’ọrọ l’aaarọ ọjọ keji iṣẹlẹ yii, iyawo Abayọmi t’awọn
eeyan pe ni iya ibeji sọ pe ọjọ karun-un
oṣu to kọja l’awọn ja, to fi di pe Abayọmi lu oun, to si ni idi niyen toun fi
k'ẹru jade.
"Bo ṣe lu mi tan ni mo ko diẹ l'ara ẹru mi kuro ninu ile. Igba to ya ti oju ẹ wa silẹ lẹyin bi ọsẹ meloo kan lo pada wa bẹ mi pe ki n ma binu. Mo si jẹ ko yee pe mi o tun le pada sinu ile naa mọ, ayafi to ba gba ile sibomi in.
"O maa n pe mi pe ki n ba oun gbe omi wa sile, ti mo si maa n gbe e lọ fun un. Ko si ija kankan mọ l'aaarin wa, ṣugbọn nnkan t'emi atiẹ jọ n fa ni pe mi o le pada sinu ile yẹn mọ, ayafi ko lọ gba ile sibomi in.
"Ọmọ meji la ṣi bi, ibeji si l'awọn ọmọ naa. Ọdun 2018 la ko de inu ile naa, ṣugbọn ọdun to kọja ni wahala iya onile wa bẹrẹ, to je pe ko si nnkan ti a mọ ọn ṣe ninu ile to to tẹ ẹ l'ọrun."
Nnkan
bi aago mejila kọja iṣẹju meji ni wọn sin Abayọmi si itẹku awọn onigbagbọ to wa
l'adugbo Iṣabọ nilu Abẹokuta.
No comments:
Post a Comment