Ẹ jẹ ka gbaruku ti AbdulRazaq lati ṣe ijọba ẹlẹẹkeji - Ọlọfa tilu Ọfa pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 28, 2021

Ẹ jẹ ka gbaruku ti AbdulRazaq lati ṣe ijọba ẹlẹẹkeji - Ọlọfa tilu Ọfa pariwo sita


Bo tilẹ jẹ pé Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ko ti i fi èròngbà rẹ hàn láti du ipo gomina lẹẹkeji, sibẹ Ọlọfa tilu Ọfa, Ọba Mufutau Gbadamọsi Eṣuwoye keji ti fi ontẹ lu Gomina AbdulRazaq lati ṣe Gómìnà ipinlẹ naa lẹẹkeji.

Ọjọ Isẹgun ti í ṣe Tusidee ana ni Ọlọfa tilu Ọfa sọrọ náà jáde wí pé àwọn iṣẹ ìdàgbàsókè ti AbdulRazaq n ṣe káàkiri ipinlẹ naa tẹ gbogbo araalu l'ọrun.

Nibi ìfilọ́lẹ̀ àjọ alaanu kan ti wọn pe ni Abdullah Abdulmajeed Foundation nilu Ọfa ni Ọba Mufutau Gbadamọsi ti sọrọ yii, pàápàá lásìkò ti alaṣẹ ati oludasilẹ àjọ náà ṣe abẹwo sí kabiyesi.

Kabiyesi ni afọju gan an mọ pé Gomina AbdulRazaq n ṣiṣẹ káàkiri ipinlẹ naa, ati pe awọn ti wọn kò fẹràn gomina ko fẹràn idagbasoke ipinlẹ naa. O ni b'awọn kan ko ba ri ipa rẹ láwùjọ, gbogbo ọmọ ìlú Ọfa pátápátá ni wọn rí ọwọ AbdulRazaq.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI