Aye o! Wọn ni Baba Ìjẹ̀ṣà, gbajugbaja òṣèré tíátà f'ipa b'ọmọ ọdún mẹrinla lo pọ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 22, 2021

Aye o! Wọn ni Baba Ìjẹ̀ṣà, gbajugbaja òṣèré tíátà f'ipa b'ọmọ ọdún mẹrinla lo pọ l'Ekoo


Teṣan ọlọpaa to wa ni Yaba n'Ipinlẹ Eko ni gbajugbaja òṣèré tíátà nni, Ọlanrewaju James Omiyinka t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ sí Baba Ìjẹ̀ṣà wa titi dasiko tá a pari ìròyìn yìí.

Baba Ijẹṣa, ẹni ọdún mejidinlaadọta la gbọ pé wọn fi ẹsùn ifipa-ba-ni-lo-pọ kan. Ọmọdébinrin ọmọ ọdún mẹrinla kan la gbọ pé Baba Ìjẹ̀ṣà n ko ibasun fún karakara, ti wọn sì latigba t'ọmọ náà ti wa lọmọ ọdún meje ni Baba Ìjẹ̀ṣà ti n dana Si abẹ rẹ karakara.

Ọmọ náà ti wọn pe orúkọ rẹ ni Ọmọbabinrin Adekọla Adekanya.

Ọjọ kọkandinlogun osu yii la gbọ pé wọn lọ fi ọrọ Baba Ìjẹ̀ṣà to awọn ọlọpaa Sabo leti, ti wọn sì láwọn yẹn ko fi ọrọ naa falẹ, ti wọn fi lọ gbe ọkunrin gbajugbaja òṣèré tíátà yii.

A gbọ pé Baba Ìjẹ̀ṣà fúnra rẹ ti jẹwọ pé lóòótọ́ ni iṣẹlẹ naaz bo tilẹ jẹ pé a kò tí ì lè fìdí rẹ múlẹ pé Baba Ìjẹ̀ṣà jẹwọ lóòótọ́.

Wọn ni kamẹra ti wọn fi máa n mọ nnkan to n lọ layika, ìyẹn CCTV lo tu àṣírí ọkunrin náà nibi tó ti n ko ibasun fún ọmọ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI