Awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ ni Kwara, láwọn ọdaràn ba n filu náà silẹ salọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 24, 2021

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ ni Kwara, láwọn ọdaràn ba n filu náà silẹ salọ


Ẹ ran àwọn ọlọpaa lọwọ - AbdulRazaq gba awọn araalu lamọnran

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq l'ọjọ Fraide anaa ti gba gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lamọnran láti máa ta àwọn ọlọpaa l'olobo to ba yẹ nipa eto aabo.

O ni ohun ti wọn ba fi to awọn leti ni wọn yóò ṣiṣẹ le lori, idi pataki to fi ni gbogbo ohun to ba n ṣẹlẹ l'agbegbe ati igberiko to jẹ mọ iwa ọdaran ni ki wọn máa fi to ọlọpaa leti.

Ana ni ijọba Kwara bẹrẹ eto idanilẹkọọ fún àwọn ọlọpaa tuntun to lé diẹ lẹgbẹrun kan (1,056) ti wọn ṣẹṣẹ gba sí iṣẹ, ta a ṣí gbọ pé ọlọpaa agbegbe ni wọn fẹẹ fi wọn ṣe, ki eto aabo le tubọ k'ẹsẹjari.


Níbẹ ni AbdulRazaq ti gbe oṣuba kare fún Ààrẹ Muhammadu Buhari lori bo ṣe f'ọwọ si eto naa, to sì ni idagbasoke nla lo jẹ.

O ni awọn ọlọpaa tuntun yii ni yóò máa mo nnkan to n ṣẹlẹ láwọn agbegbe ati igberiko káàkiri, lati le jẹ ki eto aabo lọ dáadáa.

Ọgá ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Bagega ninu ọrọ rẹ sọ pé agbekalẹ yìí kò ṣẹyin ọna lati gbogun ti iwa ọdaran l'oriṣiriṣi.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI