Awọn ọdọ tun fẹẹ jẹ anfaani nla tuntun ni Kwara l'oṣu karun-un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 2, 2021

Awọn ọdọ tun fẹẹ jẹ anfaani nla tuntun ni Kwara l'oṣu karun-un


Gbogbo eto lo ti pari patapata fun ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ileeṣẹ kan ti wọn pe ni TIIDELAB lati d'awọn ọdọ l'ẹkọọ l'ori ọna igbalode.
 
B'awọn ọdọ yoo ṣe mọ bi oyinbo ṣe n ṣe awọn nnkan imọ ẹrọ igbalode ti wọn n lo l'ori ẹrọ kọmputa, iyẹn Software Development ni wọn fẹẹ kọ gbogbo awọn to ba nifẹẹ si i.
 
Ọsẹ mẹrin ti i ṣe oṣu kan gbako la gbọ pe idanilẹkọọ naa yoo fi waye.
 
If'orukọ silẹ la gbọ pe o ti bẹrẹ lati asiko yii, ti yoo si pari l'ọjọ kẹta oṣu karun-un to n bọ lọna, ta a si gbọ pe ọjọ keji rẹ, ti i ṣe ọjọ kẹrin oṣu naa ni wọn yoo bẹrẹ idanilẹkọọ fun gbogbo awọn akopa patapata. 
 
Fun gbogbo awọn to ba fẹẹ jẹ anfaani yii, ki wọn lọ si TIIDELab Prefellowship Prep Sessions lati f'orukọ silẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI