Awọn ọdọ bọ s'aye ni Kwara, obitibiti ilẹ n'ijọba gba fun wọn lati ṣiṣẹ ọgbin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 22, 2021

Awọn ọdọ bọ s'aye ni Kwara, obitibiti ilẹ n'ijọba gba fun wọn lati ṣiṣẹ ọgbin


Gbogbo awọn ọdọ patapata kaakiri ipinlẹ Kwara ni wọn ti n gba ilu ati ijo kaakiri ipinlẹ naa bi ẹ ṣe n ka iroyin yii pẹlu bi ijọba ṣe ti pese ilẹ rẹpẹtẹ fun wọn lati ṣ'iṣẹ agbẹ ati ọgbin.
 
AWIKONKO gbọ pe ilẹ ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta ẹkita (500-hecters) n'ijọba ti pese fun gbogbo awọn ọdọ ti wọn ba nifẹẹ lati ṣe iṣẹ agbẹ ati ọgbin.
 
Kaakiri gbogbo igberiko to wa n'ijọba ibilẹ mọkandinlogun n'ipinlẹ naa l'awọn ile yii wa patapata, ta a si gbọ pe lara erongba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati din airiṣiṣẹ ṣe awọn ọdọ ku ni, ati lati mu iṣẹ agbẹ ati ọgbin lokunkundun.
 
N'igba to n s'ọrọ nibi ifilọla ipele akọkọ to waye n'ijọba ibilẹ Ifẹlodun, igbakeji Gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Kayọde Alabi sọ pe idaji awọn ọdọ ti yoo jẹ anfaani yii ni awọn obinrin, tori pe awọn ko fẹẹ ṣe e ni ẹlẹyamẹya rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI