Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣe abẹwo ibanikẹdun si gbajugbaja ọja aarin gbungbun Oro, ìyẹn Oro Central Market to wa nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ naa.
Ana ti i ṣe ọjọ Aje Mọnde yii ni ina deede ṣẹyọ lọja naa, nibi ti ọpọlọpọ ṣọọbu ti jona kọja afẹnusọ.
AWIKONKO gbọ pe awọn idọti ti wọn n da si ẹyin ọja naa, eyi tàwọn èèyàn dana sun lo mú ọkan lara awọn ṣọọbu to wa nitosi, to si da wahala nla silẹ.
Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ nibi abẹwo naa lonii gi aidunnu rẹ han, to si ṣeleri pe ijọba yoo wa nnkan ṣe lati ran awọn to padanu dukia ati ọja wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment