Àpapọ ẹgbẹ àwọn òṣèré Yorùbá l'orilẹ-ede Naijiria, ìyẹn Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria, TAMPPAN ti gba ijọba ipinlẹ Eko lamọran lati fi iya to ba tọ jẹ Ọgbẹni Ọlanrewaju James Omiyinka t'ọpọ awọn èèyàn mọ sí Baba Ìjẹ̀ṣà.
Ẹgbẹ TAMPPAN ni iwa adojutini gba a ni Baba Ìjẹ̀ṣà, gbajugbaja òṣèré tíátà náà hu, to si láwọn ko faramọ iwa buruku yii.
Ọsẹ ta a ṣẹṣẹ lo tan yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pé ọwọ àwọn tí tẹ Baba Ìjẹ̀ṣà lori ẹsun ifipabanilopọ, ati pe ọmọdebinrin ọmọ ọdún mẹrinla kan lo n ko ibasun fún karakara, ìyẹn latigba ti ọmọ náà ti wa lọmọ ọdún meje.
TAMPPAN ninu atẹjade ti wọn fi sita, eyi ti Yẹmi Amọdu to jẹ alàkóso eto iwadii ati akọsilẹ, ìyẹn Director of Research and Documentation bu ọwọ lu lo ti sọ pé ìdájọ tó bá tọ sí ọkunrin náà ni kí wọn fún ùn lati jiya ẹsẹ rẹ.
O ni gbogbo igbesẹ ti ijọba Eko ba gbe lori iṣẹlẹ naa láwọn f'ọwọ siz nitori pé ìdájọ òdodo gbọdọ f'ẹsẹ múlẹ.
Bakan naa ni ẹgbẹ TAMPPAN tun ba awọn obi ọmọ náà kẹdun bi Baba Ìjẹ̀ṣà ṣe bá a laye jẹ, leyi ti wọn fi n gba gbogbo obi ati alagbatọ lamọran láti máa faaye silẹ f'awọn ọmọ wọn lati sọrọ, ki wọn lè máa tú àṣírí àwọn èèyàn buruku to ba fẹẹ ba wọn l'ayé jẹ.
No comments:
Post a Comment