KASNATY, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ ṢEGBEYAWO ALARINRIN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 31, 2021

KASNATY, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ ṢEGBEYAWO ALARINRIN L'ABẸOKUTA


Ọjọ kinni osu kẹrin ti i ṣe ọla yii ni ọjọ ti wọn mu fun igbeyawo gbajugbaja sọrọsọrọ agbaye nni, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo tọpọ awọn ololufẹ rẹ tun n pe ni Kasnaty Sugar.

Ilu Abẹ́òkúta ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun ni eto ayẹyẹ igbeyawo naa ti fẹẹ waye ninu gbọngan ayẹyẹ ti O' Square and Suites.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ kulẹkulẹ nipa bi eto igbeyawo naa yoo ti lọ, ṣugbọn sibẹ, wọn ni Kasnaty ti pade ololufẹ tuntun lẹyin ọdun kẹta ti iyawo rẹ tẹlẹ jade laye.

Awọn to gbe iroyin naa si wa leti je ko ye wa pe Sadiat lorukọ iyawo tuntun ti Kasnaty ṣẹṣẹ pade n jẹ.

Kaadi ipe sibi ayẹyẹ eyi tàwọn oloyinbo n pe ni Invitation Card kan to tẹ wa lọwọ, nibi ta a ti ri orukọ ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun to fi ilu Abẹ́òkúta se ibugbe naa, ìyẹn Abdulkabir pẹlu Sadiat.


Àìpẹ yii la gbọ pe mọlẹbi Kasnaty ati iyawo rẹ tuntun ṣe eto mọmi-n-mọẹ.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI