Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ti sọ pe pupọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni wọn n duro lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, iyẹn APC lasiko yii nitori ti wọn mọ pe ẹgbẹ alalubarika ni.
Ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii ni wọn n tun iforukọsilẹ ṣe fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati mọ awọn ojulowo ọmọ ẹgbẹ ṣaaju asiko eto ipolongo idibo ti yoo bẹrẹ l'ọdun to n bọ.
Ana ti i ṣe Sande ni Gomina Ganduje sọrọ yii nibi ti wọn ti fi iforukọsilẹ naa lelẹ n'ipinlẹ naa, to si ni gbogbo ọmọ Naijiria lo lanfaani lati darapọ.
No comments:
Post a Comment