Ko si ọrọ meji to n lọ kaakiri igboro ipinlẹ Ogun, paapaa agbaye l'asiko yii, bi ko ṣe ti epe rabandẹ-rabandẹ ti wọn ni oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun lẹẹmẹta ọtọọtọ, Ọmọba Gboyega Nasiru Isiaka ṣe f'awọn to n sọrọ rẹ laida lori rẹdio l'Ọjọbọ ti i ṣe Tọside ana.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ori eto ori redio kan to gbajumọ daadaa nilu Abẹokuta, iyẹn Ayekootọ ti wọn maa n ṣe nileeṣẹ redio Sweet FM to jẹ ti Sẹnetọ Gbenga Ọbadara ni Gboyega Isiaka ti ṣe epe naa.
Ibeere kan ti wọn ni ki Gboyega Isiaka t'awọn ololufẹ ẹ tun mọ si GNI dahun si wi pe ṣe loootọ lo gba owo lọwọ Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu ninu idibo gomina to kọja lọ lati juwọ silẹ fun Gomina Dapọ Abiọdun to jawe olubori lo bi Isiaka ninu, ti wọn lo fi ki epe nla mọlẹ.
Ninu fọnran ibi ifọrọwerọ naa, ti wọn tun gbe jade sita lori ikanni ayelujara ti fesibuuku l'awọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu epe ọkunrin naa wi pe o ku diẹ kaato.
Gboyega Isiaka ni oun ko gba owo lati tẹle Ọmọba Dapọ Abiọdun, bẹẹ loun ko si gba owo lọwọ Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu lati juwọ silẹ fun Dapọ Abiọdun, to si l'awọn ti wọn n gbe ọrọ naa jade ko mọ nnkan ti wọn n sọ.
Fidio naa ree: GNI SỌRỌ BURUKU S'AWỌN TO N SỌRỌ RẸ LAIDA
No comments:
Post a Comment