ẸGBẸ ỌLỌDẸ ṢE IKILỌ NLA F'AWỌN ỌDARAN N'IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 28, 2021

ẸGBẸ ỌLỌDẸ ṢE IKILỌ NLA F'AWỌN ỌDARAN N'IPINLẸ OGUN


Ọga agba ẹgbẹ awọn ọlọdẹ lorilẹ-ede Naijiria, ẹka t’ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ṣorẹmẹkun John ti sọ pe ki gbogbo awọn ọdaran at’awọn to n gbero lati huwa ọdaran tete fi ilu, paapaa ipinlẹ naa silẹ ko to di pe ọwọ palaba wọn segi, to si l’awọn ko ṣetan lati foju gidi wo wọn mọ.

Ninu ifọrọwerọ ti ọkunrin naa b’AWIKONKO ṣe nilu Abẹokuta laipẹ yii lo ti sọrọ naa sita. Ẹ ka ifọrọwerọ naa siwaju.

 

AWIKONKO: Ẹ jẹ ka mọ yin.

ṢORẸMẸKUN: Orukọ mi ni Ọgbẹni Ṣorẹmẹkun John ti mo jẹ adari ẹgbẹ awọn ọlọdẹ, iyẹn Hunters Group of Nigeria, ẹka ti ipinlẹ Ogun.

AWIKONKO:

ṢORẸMẸKUN: Ẹgbẹ yii jẹ ẹgbẹ awa ti a n ṣe ọdẹ inu igbo, ko si bi igbo naa ṣe le jẹ aginju to, a maa wọ inu ẹ lati ṣe ọdẹ wa. Bi a ṣe n ṣe ọdẹ ẹranko inu igbo, bẹẹ naa la n ṣe ọdẹ fun awọn araalu lati daaboo bo ẹmi ati dukia wọn, ki ole ẹmi ati ara ma le ja wọn.

AWIKONKO: Ki lo fa a ti ẹ fi da ẹgbẹ yii silẹ labẹ ijọba

ṢORẸMẸKUN: Iṣẹ ọdẹ ti wa tipẹ, ki wọn to o bi awọn babanla wa ni wọn ti n ṣiṣẹ ọlọdẹ, kumọ lasan ni wọn fi n ṣe ọdẹ nígba yẹn, ko to di pe wọn bẹrẹ si i lo ibọn. A ti n ṣe iṣẹọdẹ yii laaarin ara wọn, ṣugbọn n’igba to di pe awọn ajinigbe bẹrẹ si i pọ si i, la fi wo o pe ani lati f’imọ ṣọkan lati le ran awọn ijọba lọwọ, ki eto aabo le tubọ gbe pẹẹli si i. Pupọ awọn aṣiri awọn ajinigbe to n tu lo jẹ pe awa la n fun awọn agbofinro lọwọ, ti aṣiri awọn oniṣẹ ibi si n tu sita. N’igba ti ijọba ri awọn iṣẹ ta a n ṣe lo mu ki wọn sọ pe ka gbe iwe abadofin wa sile igbimọ aṣofin, ti a si gbe e lọ, a si ti la ipele keji kọja. Bi ki i ba a ṣe ti korona to wa nita ni, o yẹ ki wọn ti gbe e sita f’awọn araalu lati mọ, eyi ti wọn tun n pe ni Public Hearing.

AWIKONKO: Se ka sọ pe tori awọn ajinigbe lẹ ṣe pinnu lati f’orukọ ẹgbẹ yin silẹ labẹ ijọba?

ṢORẸMẸKUN: Ki i ṣe tori ẹ nikan, bi ẹ ba wo ẹgbẹ wa daadaa, a jẹ ẹgbẹ to n ṣe iṣori fun araalu nipa didaabo bo ẹmi ati dukia araalu. Bi a ba si wo awọn darandaran yii, pupọ ninu wọn lo jẹ pe nnkan ija oloro ni wọn n gbe ti awa gan ko  fọwọkan ri. Bi ida, ibn AK, fa ni won n gbe kiri, bi wọn ba gbe eeyan, ti wọn ko ba ri owo gba lọwọ ẹ, ṣe ni wọn maa pa ẹni naa, eyi lo ṣe pọn dandan lati mojuto agbegbe wa. A ko si fọwọ yẹpẹrẹ mu.

AWIKONKO: Ki l’awọn nnkan amuṣagbara yin?

ṢORẸMẸKUN: Ọlọrun ni alaabo wa nipasẹ adura. Ẹni ti ko ba wọ inu igbo ri, ko le tẹsẹ bọ ọ lojiji, ẹni ti wọn ko ba bi sínu iṣẹ ọdẹ ko le wọnu igbo, wọn bi wa sinu ẹ ni.

AWIKONKO: Bawo lo ṣe di pe ẹ ni ọga agba apapọ

ṢORẸMẸKUN: A ti wa t’ipẹ bi mo ṣe sọ, ṣugbọn ka le wa ni iṣọkan la fi pinu lati wa papọ. Ijọba si ri i pe a n ṣiṣẹ takuntakun.

AWIKONKO: Ipo wo ni eto aabo wa, paapaa n’ipinlẹ Ogun

ṢORẸMẸKUN: Ka dupẹ lọwọ Ọlọrun, tori pe t’ọsan t’oru lawa eleto aabo patapata fi n ṣiṣẹ papọ. Gbogbo wa la jọ ni ajọṣepọ to dan mọnran. Eto aabo wa duro digbi. Ajọṣepọ awa at’awọn eleto aabo yooku dan mọnran gidi, idi ree ti Ọlọrun ṣe n fun wa ṣe.

AWIKONKO: Ki ni afojusun yin bi ẹ ṣe di ọga agba ẹgbẹ ọlọdẹ n’ipinlẹ Ogun

ṢORẸMẸKUN: Ohun ti mo fẹ ki gbogbo eeyan mọ ni pe awa ọlọdẹ ti ṣetan lati ri i pe eto aabo jẹ gboogi fun wa, ki awọn araalu le sun asundọkan lai ni ipaya ninu, ki iwa ọdaran si d’ohun igbagbe patapata.

AWIKONKO: Ṣe ẹyin naa n gb’awọn eeyan sinu ẹgbẹ yin, ati pe iru awọn wo lẹ n gba?

ṢORẸMẸKUN: Bi gbogbo ilu ba jẹ alaabo, ko pọ ju rara. Ẹni ti ki ba a ṣe ọdẹ le darapọ mọ ẹgbẹ wa, bi iru ẹni bẹẹ ba ti ni iwa to dara lọwọ, táwọn agbaagba adugbo rẹ si le f’ọwọ sowọpọ pẹlu ẹ

AWIKONKO: Amọran yin f’awọn araalu

ṢORẸMẸKUN: Awọn ọdaran ni maa kọkọ gba lamọran pẹ ki wọn lọ jawọ tabi ki wọn fi ipinlẹ Ogun yii silẹ fun wa, tori pe a ko ni f’oju rere wo wọn mọ. Bẹẹ la fi n jẹ ko ye awọn araalu pe asiko alaafia lo de fun wọn yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI