AMỌTẸKUN YINBỌN F'ỌLỌPAA L'ỌYỌỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 4, 2021

AMỌTẸKUN YINBỌN F'ỌLỌPAA L'ỌYỌỌ


Kayeefi lọrọ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun n'ilu Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ṣi n jẹ f'awọn to gbọ lori bo ṣe yinbọn fun ọlọpaa.
 
Ibrahim Ogundele ti wọn ni agbegbe Isalẹ-Ọyọ lo wa la gbọ pe awọn gendekunrin kan pe lagbegbe Sanga nilu Ọyọ lati wa a daabobo wọn nibi kanifa (carnival) opin ọdun ti wọn ṣe l'ọsẹ to kọja yii.
 
Awọn araalu ni wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa lati wa a tu awọn eeyan naa ka, ti wọn si ni Fatai Yẹkini ni ọlọpaa ti wọn ran lọ sibẹ.
 
Ibi ti wọn ni Yẹkini ti n ba wọn fa ọrọ yii la gbọ pe Ibrahim ti yinbọn fun un lẹsẹ, t'awọn ẹlẹyinju aanu si sare gbe e lọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju lọwọ.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Gbenga Fadeyi f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni awọn ti ti Amọtẹkun naa mọle lati fọrọ wa a lẹnu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI