...ẹsun jìbìtì ni wọn fi kan an
Ìka abamọ ni Pasitọ kan tí wọ́n pè orúkọ ẹ ní Odenigbo Theophilus mú sẹnu lọ́jọ́ Ẹtì tí í ṣe Fraidee àná nígbà tí ikẹ ẹjọ́ gíga tipinlẹ Ọ̀yọ́ tó wà n'ilu Ibadan júù sẹwọn ọdún méje gbáko pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára.
Òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì kan, Òjó Gbádébọ̀ là gbọ́ pé Theophilus lu ni jìbìtì miliọnu kan náírà.
AWIKONKO gbọ pé ṣe NI Theophilus lọ tán Gbádébọ̀ láti bá a fi owó ẹ dokoowo nínú epo rọbi, ṣùgbọ́n wọn ní bo se gba owó náà tán lo bẹ̀rẹ̀ si í jaye bo ṣe wù ú.
Wọn ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin náírà ni Theophilus sọ pé Gbádébọ̀ yóò máa gba loṣooṣu, ṣùgbọ́n tó padà yí ìpinnu náà padà. Wọn ní Gbádébọ̀ kò bmgba náírà kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kò rí owó ẹ gba padà, èyí ló jẹ́ kó lọ fọrọ náà tó awọn ọlọpaa létí.
Nígbà tó ń gbé idajọ kalẹ, Onidajọ Muniru Owolabi pàṣẹ pé kí Theophilus lo fi ẹ̀wọ̀n ọdún méje péré gbára pẹlu iṣẹ àṣekára, nítorí pé àwọn ẹri ẹ̀sùn tí wọn fi kan án kò ṣeé fọwọ́ rọ sẹ́yìn.
No comments:
Post a Comment