WAHALA NLA DE B'AWỌN ỌDARAN BI ỌGA ỌLỌPAA TUNTUN ṢE WỌ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 31, 2020

WAHALA NLA DE B'AWỌN ỌDARAN BI ỌGA ỌLỌPAA TUNTUN ṢE WỌ KWARA


Laipẹ yii ni ọga ọlọpaa tuntun bẹrẹ iṣẹ n'ipinlẹ Kwara, iyẹn Mohammed Lawal Bagega.
 
Ni kete to bẹrẹ iṣẹ lo ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọlọpaa bẹ ẹ pe oun fẹẹ foju kan awọn ọdaran tuntun ti wọn n da alaafia ipinlẹ naa laamu, koun si le fi wọn j'ofin, ati lati jẹ ki wọn mọ pe eto aabo ipinlẹ naa lasiko toun ki i ṣe ṣereṣere rara.
 
Loju ẹsẹ l'awọn ọlọpaa naa ti fọnka s'igboro, ti wọn si bẹrẹ si i wọ ahere awọn ọdaran ati oniṣẹ buburu lọ, ti wọn si ko pupọ ninu wọn.
 
N'igba to n sọrọ lana ti i ṣe Wẹsidee, ọga ọlọpaa naa, Mohammed Bagega sọ pe oun ko le laju silẹ lati jẹ k'awọn ọdaran maa rin yan fanda pẹlu awọn eeyan gidi lawujọ, to si ni k'awọn ti ọwọ palaba wọn ko ba ti i segi tete filu silẹ lọ sibomi in.
 
O l'awọn tọwọ tẹ ti wa lahamọ, nibi ti wọn ti n ka boroboro, to si ni lẹyin iwadii  ni wọn yoo fiya to tọ jẹ wọn labẹ ofin orilẹ-ede yii.
 
Lara awọn tọwọ palaba wọn segi ni Akewuṣọla Suleiman ti wọn lọwọ tẹ nibi to ti lọ ji awọn irinṣẹ agbenawọle pẹlu oorun, iyẹn Solar Panel t'ijọba ṣe f'awọn araalu, ti wọn si l'awọn yooku ẹ ti na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI